"Kò bá dáa kẹ pa ìyá mi dípò tẹ fi pa ọmọ rẹ̀, ìyàwó ọmọ àti oyún oṣù mẹ́rin"

Owó pínpín dá rògbodìyàn òṣèlú sílẹ̀ ní Ede, ẹ̀mí olóyún, ọlẹ̀ inu rẹ àti ọkùnrin kan ba rìn
Laasigbo oselu to n ja rainrain nilu Ede, nilẹ nipinlẹ Osun tun ti ba ibo miiiran yoo.
Idi ni pe awọn mọlẹbi kan ti fẹsun kan, Asofin Kofoworola Babajide, tii se olori ọmọ ẹgbẹ oselu to kere julọ nile asofin ipinlẹ Osun.
Ẹsun ti n fi kan asofin ọhun ni pe o ṣeku pa awọn eeyan meji, paapajulọ, ọkunrin kan ati obinrin kan pẹlu oyun oṣu mẹrin ninu.
Orukọ awọn oloogbe naa ni Abideen Olalekan ati Kafayat Olalekan ti wn wa latinu idile kannaa.
Nigba ti awọn ẹbi ọhun n ba BBC Yoruba sọrọ nilu Ede, lori bawọn ọmọ wọn ṣe pade iku ojiji, wọn na ika aleebu sawọn ọlọpaa ati Asofin kan.
Asofin naa ni Hon Kofoworola Babajide, tii se olori ọmọ ẹgbẹ oselu to kere julọ nile asofin ipinlẹ Osun.
Bawo ni isẹlẹ naa se waye?
Awuyewuye naa ni awọn ẹbi yii lo bẹrẹ lasiko ipade wọọdu ẹgbẹ oselu PDP to waye nilu Ede lọjọ Ẹti.
Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni wọn lo bu ifọti lu ọkan lara awọn oluranlọwọ fun asofin Babajide Kofoworola lasiko ipade ọhun.
Igbesẹ yii si lo bi rogbodiyan to tẹle, eyi to lọwọ awọn janduku kan ninu, ti wọn si ni asofin naa ke sawọn agbofinro lati wa yanju aawọ naa.
Agboole Ate, Odolu to wa nijọba ibilẹ Ariwa Ede si ni wọn ni wọn ti pa Abideen ni oru mọjumọ ọjọ Ẹti ati Kafayat, obinrin oloyun naa.
Gẹgẹ bi wọn ti salaye fun BBC Yoruba, awọn eeyan ti ọrọ iku Abideen àti Kafayat Ọlálékan n bi ninu, lo fa wahala ati rogbodiyan ni alẹ ọjọ ẹti ni ìlu Ede.
Wọn ni awọn eeyan naa si lo dana sun ile ati dukia Baba asofin Kofoworola, ti wọn ko sí ti ri baba naa titi di akoko yii.
Amọ ko si sẹni to le sọ bóyá wọn sun mọ ile ni tabi wọn ji gbe lọ.
A tun gbọ pe ọna lati gbẹsan ile obi asofin ti wọn dana sun naa, lo mu awọn janduku miran lọ dana sun ilé ati dukia Silifatu Ọlalekan, ti o jẹ iya Abideen to ti di oloogbe.
Bẹẹ ba gbagbe, ninu iroyin ta mu wa fun yin saaju lori isẹlẹ yii, Asofin Kofoworola sọ fun BBC Yoruba pe arabinrin Silifatu Olalekan naa lo n sẹ epe fun ara awọn alatilẹyin oun, lasiko ipade ọhun eyi to jẹ ibẹrẹ aawọ naa.

Ọrọ owo kan ti wọn gbe fun Asofin Kofoworola, ti ko pin fun awọn ọdọ lo da ija silẹ - Silifatu Olalekan
Arabinrin Silifatu Olalekan, tii se iya Abideen, ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba ni oun ati Aṣofin Kofoworola Babajide jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP.
O ni awọn dijọ n ṣe isẹ pọ lasiko idibo gomina to gbe Sẹnetọ Ademola Adeleke wọle gẹgẹ bi gomina tuntun nipinlẹ naa ni.
Silifatu tẹsiwaju pe ọrọ owo lo da ija silẹ laarin awọn ọdọ ẹgbẹ oṣelu PDP ati aṣofin naa.
O ni wọn gbe owo kan fun aṣofin naa lati pin fun awọn ọmọ ẹgbẹ naa.
“Wọn fun wa ni owo ni wọọdu, ti mo si jẹ ọkan lara asoju PDP fun Jide Akọgun (Kofoworola Babajide).
Lẹyin idibo gomina to gbe Ademola Adeleke wọle, ni wọn fun wa ni owo yii pe ka fi ra nkan jẹ.
Amọ wọn ko fun awọn wọọdu yii ni owo wọn, emi ni mo si polongo lọ lati ri pe ki wọn ba wa dibo fun ẹgbẹ yii."
‘”Awọn ẹgbẹ wa ko owo fun Jide Akọgun lọwọ pe ki awọn ọdọ fi ra nkan jẹ amọ ni awn ọdọ yii n beere owo naa lọwọ mi.
Asofin naa wa n sọrọ pe owo ki ni wọn n beere lọwọ oun, oun ti na owo yẹn, tawọn ọdọ si yari pe mo ko awọn wa fun iya jẹ ni.
Bi ọkunrin kan ti orukọ rẹ jẹ Nureni ṣe gba ọkan loju lara awọn ọdọ ẹgbẹ niyẹn."
Silifatu ni ko pẹ ni aṣofin naa ke sawọn ọlọpaa lati wa mu awọn ọmọ ẹgbẹ pe awọn ti lu oun ati pe awọn kan ti yin ibọn.
O ni nikete tawọn ọlọpaa de, ni wọn ni awọn ko ri apẹẹrẹ pe ija wa nibi ti awọn wa, ni wọn ba ti wọn lọ.

Ki lo wa fa iku Kafayah àti Abideen Olalekan?
Silifatu ni ọmọ oun n ti ibi isẹ birikila bọ ni, lẹyin ti o ba awọn kan gba iwe ẹri, ni awọn ọlọpaa, ti aṣofin Kofoworola pe wa si yin ibọn fun, nibi to ti n gbe iwe naa le wọn lọwọ.
“Bi Akọgun to ni oun lọ Osogbo, se pada de niyẹn, ti o si ko awọn ọlọpaa SARs wa, to si na ọwọ pe ki awọn saasi yin ibọn fun Abideen.
Mo ba bu SARs yii so, lo ba fẹ yin emi na ni ibọn.”
‘Ọlọpaa ti asofin pe wa lati Osogbo lo yinbọn pa ẹgbọn mi ati iyawo aburo mi’
Olalekan Rukayat Olasoji, ti ọrọ naa se oju rẹ, naa ba akọroyin BBC Yoruba sọrọ.
O ni pe ìpade ẹgbẹ woodu ti ẹgbẹ oṣelu PDP ni awọn n se lọwọ, ki ariyanjiyan to bẹrẹ lori pipin owo oselu..
Rukayat ni awuyewuye naa lo fa wahala ti Asofin Koworola si gbà ilu Osogbo lọ lati lọ ko awon ọlọpa miran wa yatọ sí ọlọpa ilu Ede.
O ni wọn yinbọn pa ẹgbọn ati ìyàwó aburo ohun, eyi ti orukọ rẹ njẹ Kayafah.
Iwadi BBC Yoruba fihan pe Olalekan Ibrahim Tunde, ti wọn pa iyawo rẹ pẹlú oyun osu mẹrin ninu, jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC tọkantọkan.
O wa pe fún idajọ ododo lori iku ti o pa iyawo ati ẹgbọn rẹ.
Bakanna lo tun ra ọwọ ẹbe sí ìjọba ìpínlè Osun pe kí wọn gba oun lọwọ asofin Kofoworola Babajide, to tun dun kukulaja mọ oun lati gba ẹmi oun.

‘Abideen Olalekan kii se onijagidijagan rara’
Awọn ara ìlu ti ọrọ naa se oju wọn, Yinusa Atanda ati Wakilat Owolabi ni oloogbe Abideen Ọlálékan kìí se onijakidijagan eniyan.
Bakan naa ni wọn fidi rẹ mulẹ pe osisẹ Birikila, to n ba ni kọle ni.
Silifatu Olalekan, ti o je iya fun Abideen ati iya ọkọ fun Kafayah, naa wa rawọ ẹbẹ sí ìjọba ìpínlẹ Osun ati gbogbo ọmọ Naijiria pe ki wọn gba oun.
Awọn abiyamọ mejeeji naa ni ko yẹ ki awọn ọlọpaa yju sibi isẹlẹ naa lati ma yinbọn, ti awọn si padanu ẹmi ọmọ ati iyawo ọmọ lọna buruku bẹẹ.
Asofin Kofoworola Babajide ni irọ ni gbogbo sun ti wọn fi kan oun
Olori awọn asofin latinu ẹgbẹ oṣelu PDP, to kere julọ nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Osun, Onarebu Adewumi Babajide Koworola naa tako awọn ẹsun yii.
Asofin naa, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ní gbogbo ẹṣun ti awọn ẹbi olóògbé fi kan oun, lo je Irọ nla.
Ọnarebu Kofoworola wa ro awọn ọlọpa lati ṣe awari bàbá oun ati awọn to dana sun dukia rẹ.

Kí ni Ọlọ́pàá sọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà?
Alukoro ileese olopaa Yemisi Opalola ti fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Opalola ni kete ti iroyin naa de eti Ọgá agba ọlọpaa ipinlẹ Osun, ni wọn tu ikọ ọlpaa to n paraaro ilu, to lọ se isẹ ibi naa ka.
O ni iwadi ṣi nlọ lọwọlọwọ lori isẹlẹ naa.
Alukoro ileesẹ ọlọpaa naa wa fi da awọn mọlẹbi atawọn araalu loju pe ọrọ naa ko ni lọ bẹẹ.
“Awon to huwa yii yoo fimu kata ofin. A maa ri daju pe idajọ ododo fidi mulẹ lori isẹlẹ naa.”

















